Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Míkà 2:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkan kan nínú ìjọ Olúwa,tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò.

6. “Ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀lẹ̀,” ni àwọn Wòlíì wọn wí.“Ẹ má ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;kí ìtìjú má ṣe le bá wa”

7. Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jákọ́bù:“Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí?Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nì wọ̀nyí?”“Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rerefún ẹni tí ń rìn déédé bí?

8. Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìdebí ọ̀tá sí mi.Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu,bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.

9. Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mikúrò nínú ilé ayọ̀ wọn,ẹ̀yin sì ti gba ògo mi,kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.

10. Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ!Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín,nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́yóò pa yín run,àní ìparun kíkorò.

11. Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé,‘Èmi yóò sọ tẹ́lẹ̀ fún ọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti bíà,’òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí!

Ka pipe ipin Míkà 2