Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 7:7-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Jósúà sì wí pé, “Háà, Olúwa Ọlọ́run alágbára, nítorí i kiín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá a Jọ́dánì, láti fi wọ́n lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́; láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdì kéjì Jọ́dánì?

8. Olúwa, kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Ísírẹ́lì sì ti sá níwájú ọ̀ta a rẹ̀.?

9. Àwọn Kénánì àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?”

10. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojú bolẹ̀?

11. Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn.

12. Ìdí nì-yí tí àwọn ará Ísírẹ́lì kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀ta wọn; wọ́n yí ẹ̀yín wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀ta a wọn nítorí pé àwọn gan-an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò se pé ẹ̀yin pa ohun ìyàṣọ́tọ̀ run kúrò ní àárin yín.

13. “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárin yín, Ìwọ Ísírẹ́lì. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀ta a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò.

14. “ ‘Ní òwúrọ̀ kí ẹ mú ará yín wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan.

15. Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàṣọ́tọ̀ náà, a ó fi iná paárun, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Ísírẹ́lì!’ ”

16. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì, Jóṣúà mú Ísírẹ́lì wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Júdà.

17. Àwọn agbo ilé e Júdà wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sérátì. Ó sì mú agbo ilé Sérátì wá ṣíwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Símírì.

18. Jóṣúà sì mú ìdílé Símírì wá ṣíwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Sérà ti ẹ̀yà Júdà.

19. Nígbà náà ní Jóṣúà sọ fún Ákánì pé, “Ọmọ mi fi ògo fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí o sì fi ìyin fún un. Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi.”

Ka pipe ipin Jóṣúà 7