Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, Jóṣúà ati gbogbo àwọn Ísírẹ́lì sí kúrò ní Sítímù, wọ́n sì lọ sí etí odò Jọ́dánì, wọ́n sì pa ibùdó síbẹ̀ kí wọn tó kọjá.

2. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta àwọn olórí la àárin ibùdó já.

3. Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Nígbà tí ẹ bá rí àpótí i májẹ̀mú Olúwa, Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò o yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e.

4. Ẹyin yóò lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà, torí pé ẹ̀yin kò gba ọ̀nà yìí tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n àlàfo gbọdọ̀ wà ní àárin yín àti àpótí náà, tó bí ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún un mítà (1000).”

5. Jóṣúà sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, Olúwa yóò ṣe ohun ìyanu ní àárin yín.”

6. Jóṣúà sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà, kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn.

7. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì; kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lúù rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Móṣè.

8. Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà: ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jọ́dánì, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà.’ ”

9. Jóṣúà sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín.

10. Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárin yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì, Hífì, Pérésì, Gágáṣì, Ámórì àti Jébúsì jáde níwájú u yín.

Ka pipe ipin Jóṣúà 3