Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 24:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Jóṣúà pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọ ní Ṣékémù. Ó pe àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, onídájọ́ àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.

2. Jóṣúà sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Térà bàbá Ábúráhámù àti Náhórì ń gbé ní ìkọjá odò, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà.

3. Ṣùgbọ́n mo mú Ábúráhámù baba yín kúrò ní ìkọjá odò mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kénánì, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Ísáákì,

4. Èmi sì fún ní Ísáákì, mo fún ní Jákọ́bù àti Ísáù, mo sì fún Ísáù ní ilẹ̀ orí òkè Séírì, Ṣùgbọ́n Jákọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì.

5. “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mósè àti Árónì, mo sì yọ Éjíbítì lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.

6. Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Éjíbítì, ẹ wá sí òkun, àwọn ará Éjíbítì lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun pupa.

7. Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárin yín àti àwọn ará Éjíbítì, ó sì mú òkun wá sí orí i wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Éjíbítì. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní ihà fún ọjọ́ pípẹ́.

8. “ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jọ́dánì. Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò ní wájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn.

9. Nígbà tí Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù, múra láti bá Ísírẹ́lì jà, ó ránṣẹ́ sí Bálámù ọmọ Béóríù láti fi yín bú.

10. Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Bálámù, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín ṣíwájú àti ṣíwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

11. “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ ré kọjá Jọ́dánì, tí ẹ sì wá sí Jẹ́ríkò. Àwọn ará ìlú Jẹ́ríkò sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Ámórì, Pérísì, Kénánì, Hítì, Gígásì, Hífì àti Jébúsì. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

12. Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọbá Ámórì méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín.

13. Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà ólífì tí ẹ kò gbìn.’

14. “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò àti ní Éjíbítì kúrò, kí ẹ sì máa sin Olúwa.

15. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin Olúwa nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò, tàbí òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, Olúwa ni àwa yóò máa sìn.”

16. Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ Olúwa sílẹ̀ láti sin òrìṣà.!

17. Nítorí Olúwa Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Éjíbítì, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárin gbogbo orílẹ̀ èdè tí a là kọjá.

Ka pipe ipin Jóṣúà 24