Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 22:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nígbà tí Ákánì ọmọ Sérà ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọtọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Ísírẹ́lì nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ”

21. Nígbà náà ni Rúbénì, Gádì àti ẹ̀yà Mánásè sọ nínú ìdáhùn wọn fún àwọn olórí Ísírẹ́lì pé.

22. Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run! Olúwa Ọlọ́run àwọn ọlọ́run, Òun mọ̀ jẹ́ kí Ísírẹ́lì kí ó mọ̀! Bí èyí bá wà ní ìsọ̀tẹ̀ tàbí àìgbọ́ràn sí Olúwa, ẹ má ṣe dá wa sí ní òní yìí.

23. Bí àwa bá ti mọ pẹpẹ wa láti yí padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa àti láti rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ jíjẹ, tàbí ẹbọ àlàáfíà ní orí rẹ, kí Olúwa fún ara rẹ̀ gba ẹ̀san

24. “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Àwa ṣe èyí ní ìbẹ̀rù pé ní ọjọ́ tí àwọn ọmọ yín yóò wí fún wa pé, ‘Kí ni ẹ̀yín ní ṣe pẹ̀lú Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì?

25. Olúwa ti fi Jódánì ṣe ààlà láàárin àwa àti ẹ̀yin-àwọn ọmọ Réúbénì àti àwọn ọmọ Gádì! Ẹ kò ni ní ìpín nínú Olúwa.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ yín lè mú kí àwọn ọmọ wa dẹ́kun láti máa bẹ̀rù Olúwa.

26. “Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, Ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ọrẹ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’

27. Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàárin àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa.’

28. “Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé: Ẹ wo àpẹrẹ pẹpẹ Olúwa, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ọrẹ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrin àwa àti ẹ̀yin.’

Ka pipe ipin Jóṣúà 22