Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 17:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ní ìpín ẹ̀yà Mànásè tí í ṣe àkọ́bí Jósẹ́fù, fún Mákírì, àkọ́bí Mánásè. Mákírì sì ni babańlá àwọn ọmọ Gílíádì, tí ó ti gba Gílíádì àti Básánì nítorí pé àwọn ọmọ Mákírì jẹ́ jagunjagun ńlá.

2. Nítorí náà ìpín yìí wà fún ìyókù àwọn ènìyàn Mánásè: ní agbo ilé Ábíésérì, Hélékì, Ásíríélì, Sékémù, Héférì àti Ṣémídà. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọmọ ọkùnrin Mánásè ọmọ Jósẹ́fù ní agbo ilé wọn.

3. Nísinsìn yìí Sẹloféádì ọmọ Héférì, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírì, ọmọ Mánásè, kò ní ọmọkùnrin, bí kò se àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́: Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tásà.

4. Wọ́n sì lọ bá Élíásárì àlùfáà, Jóṣúà ọmọ Núnì, àti àwọn olórí wí pé, “Olúwa pàṣẹ fún Mósè láti fún wa ní ìní ní àárin àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa.

5. Ìpín ilẹ̀ Mànásè sì jẹ́ ìsọ̀rí mẹ́wàá ní ẹ̀bá Gílíádì àti Básánì ìlà oòrùn Jọ́dánì,

6. Nítorí tí àwọn ọmọbìnrin ẹ̀yà Mànásè gba ìní ní àárin àwọn ọmọkùnrin. Ilẹ̀ Gílíádì sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ọmọ Mánásè.

7. Agbégbé Mánásè sì fẹ̀ láti Áṣírìu títí dé Míkímẹ́tatì ní ìlà oòrùn Sékémù. Ààlà rẹ̀ sì lọ sí ìhà gúsù títí tó fi dé ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé ní Tápúà,

8. (Mánásè lo ni ilẹ̀ Tápúà, ṣùgbọ́n Tápúà fúnra rẹ̀ to wa, ni ààlà ilẹ́ Mánásè jẹ ti àwọn ará Éfúráímù.)

9. Ààlà náà sì tún tẹ̀ṣíwájú lọ sí gúsù dé Kana-Ráfínì. Àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti Éfúráímù wà ní àárin àwọn ìlú Mánásè, ṣùgbọ́n ààlà Mánásè ni ìhà àríwá Ráfínì, ó sì pin sí òkun.

10. Ìhà gúsù ilẹ̀ náà jẹ́ ti Éfúráímù, ṣùgbọ́n ìhà àríwá jẹ́ ti Mánásè. Ilẹ̀ Mánásè dé òkun, Ásérì sì jẹ́ ààlà rẹ̀ ní àríwá, nígbà Ísákárì jẹ́ ààlà ti ìlà-oòrùn.

11. Ní àárin Ísákárì àti Ásérì, Mánásè tún ni Bẹti-Ṣánì, Íbílémù àti àwọn ènìyàn Dórì, Énídórì, Táánákì àti Mégídò pẹ̀lú àwọn abúlé tí ó yí wọn ká (ìkẹ́ta nínú orúkọ wọn ní Náfótì).

Ka pipe ipin Jóṣúà 17