Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 11:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mósè pàṣẹ fún Jóṣúà, Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mósè.

16. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà gba gbogbo ilẹ̀ náà: ilẹ̀ òkè, gbogbo Nẹ́gébù, gbogbo agbégbé Gósénì, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ísírẹ́lì,

17. láti òkè Hálakì títí dé òkè Séírì, sí Báálì-Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì ní ìsàlẹ̀ òkè Hámónì. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n.

18. Jóṣúà sì mú gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí jagun ní ọjọ́ pípẹ́.

19. Kò sí ìlú kan tí ó bá àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àdéhùn àlàáfíà, àyàfi àwọn ará Hífì tí wọ́n ń gbé ní Gíbíónì, gbogbo wọn ló bá a jagun.

20. Nítorí Olúwa fúnrà rẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Ísírẹ́lì jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátapáta, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

21. Ní àkókò náà ni Jóṣúà lọ tí ó sì run àwọn ará Ánákì kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hébúrónì, Débírì, àti ní Ánábù, àti gbogbo ilẹ̀ Júdà, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Ísírẹ́lì. Jóṣúà sì run gbogbo wọn pátapáta àti ìlú wọn.

22. Kò sí ará Ánákì kankan tí ó sẹ́kù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì: bí kò ṣe ní Gásà, Gátì àti Ásídódù.

23. Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà sì gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè, ó sì fi fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀-ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nípa ẹ̀yà wọn.Ilẹ̀ náà sì sinmi ogun.

Ka pipe ipin Jóṣúà 11