Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóṣúà 10:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àwọn ará Gíbíónì sì ránṣẹ́ sí Jóṣúà ní ibùdó ní Gílígálì pé: “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín silẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Ámórì tí ń gbé ní orílẹ̀ èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”

7. Bẹ́ẹ̀ ni Jóṣúà gòkè lọ láti Gílígálì, pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

8. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn; Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojú kọ ọ́.”

9. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gílígálì, Jóṣúà sì yọ sí wọn lójijì.

10. Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Ísírẹ́lì, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gíbíónì. Ísírẹ́lì sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹti-Hórónì, ó sì pa wọ́n dé Ásékà, àti Mákédà.

11. Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Ísírẹ́lì ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Bẹti-Hórónì títí dé Ásékà, Olúwa rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọju àwọn tí àwọn ará Ísírẹ́lì fi idà pa lọ.

12. Ní ọjọ̀ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Ámórì lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, Jóṣúà sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Ísírẹ́lì:“Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gíbíónì,Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Áíjálónì.”

13. Bẹ́ẹ̀ ni òòrùn náà sì dúró jẹ́,òṣùpá náà sì dúró,títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀ta rẹ̀,gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jáṣárì.Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan.

14. Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣaájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí Olúwa gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú Olúwa jà fún Ísírẹ́lì!

Ka pipe ipin Jóṣúà 10