Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jóẹ́lì 2:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nítòótọ́, Olúwa yóò dá wọn lóhùn:“Yóò sì wí fun àwọn ènìyàn rẹ̀ pé,Wò ó èmi yóò rán ọkà, àti ọtí wáìnì tuntun,àti òróró síi yín, a ó sì fi wọn tẹ́ yín lọ́rùn:èmi kì yóò si fí yín ṣe ẹ̀gan mọ́ láàrin àwọn aláìkọlà.

20. “Ṣùgbọ́n èmi yóò lé ogun àríwá jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ yín,èmi yóò sì lé e lọ sí ilẹ̀ tí ó ṣá, tí ó sì di ahoro,pẹ̀lú ojú rẹ̀ sí òkun ìlà oòrùn,àti ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìwọ̀ oòrùn òkun.Oòrùn rẹ̀ yóò sì gòkè,òórùn búburú rẹ̀ yóò sì gòkè.”Nítòótọ́ ó ti ṣe ohun ńlá.

21. Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀;jẹ́ kí inú rẹ̀ dùn kí o sì yọ̀,nítorí Olúwa ti ṣe ohun ńlá,

22. Ẹ má bẹ̀rù, ẹranko igbó,nítorí pápá-oko ihà ń rú,nítorí igi ń so èso rẹ̀, igi ọ̀pọ̀tọ́àti àjàrà ń so èso ipá wọn.

23. Ǹjẹ́ jẹ́ kí inú yín dùn, ẹ̀yin ọmọ Ṣíónì,ẹ sì yọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run yín,nítorí ó ti fi àkọ́rọ̀ òjò fún yín bí ó ti tọ́,Òun ti mú kí òjò rọ̀ sílẹ̀ fún un yín,àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní oṣù kìn-ín-ní.

24. Àwọn ilẹ̀ ìpàkà yóò kún fún ọkà;àti ọpọ́n wọn nì yóò ṣàn jádepẹ̀lú ọti wáìnì tuntun àti òróró.

25. “Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín.Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewéọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòro ajẹnirun mìíràn ti fi jẹàwọn ogun ńlá mí tí mo rán sí àárin yín.

26. Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, titi ẹyin yóò fi yóẹ ó sì yín orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín,ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò;ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.

Ka pipe ipin Jóẹ́lì 2