10. Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń sọ̀fọ̀ nítorí,a fi ọkà ṣòfò:ọtí wáìnì tuntún gbé, òróró ń bùṣe.
11. Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀;ẹ pohùn réré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà,nítorí àlìkámà àti nítorí ọkà báálì;nítorí ìkórè oko ṣègbé.
12. Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù;igi pómégánátì, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú,àti igi ápíílì, gbogbo igi igbó ni o rọ:Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn
13. Ẹ di ara yín ni àmùrè,sí pohùn réré ẹkún ẹyín àlùfáà:ẹ pohùn réré ẹkún, ẹyín ìránṣẹ́ pẹpẹ:ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀,ẹ̀yin ìrànsẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ jíjẹ àti ọrẹmímú dúró ní ilé Ọlọ́run un yín.
14. Ẹ yà ààwẹ̀ kan sí mímọ́,ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú,ẹ pe àwọn àgbà,àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náàjọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín,kí ẹ sí képe Olúwa
15. A! Fún ọjọ́ náà,nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmare.
16. A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájúojú wá yìí,ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú iléỌlọ́run wá?
17. Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn,a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀;nítorí tí a mú ọkà rọ.
18. Àwọn ẹranko tí ń kerora tó!Àwọn agbo ẹran dààmú,nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko;nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.
19. Olúwa, sí ọ ni èmi o ké pè,nítorí iná tí run pápa oko tútú ihà,ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó.
20. Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú:nítorí tí àwọn iṣàn omi gbẹ,iná sí ti jó àwọn pápá oko ihà run.