Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 8:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbàtirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèémọ àkókò ìsípòpadà wọn. Ṣùgbọ́n àwọnènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́.

8. “ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbàtí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọnakọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn

9. Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dàwọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa. Irú ọgbọ́nwo ló kù tí wọ́n ní?

10. Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fúnàwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọnfún àwọn ẹlòmíràn láti èyí tó kéréjù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọnni èrè àjẹjù ń já lẹ́nu; àwọn wòlíìàti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.

11. Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́bí èyí tí kò jinlẹ̀.“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,nígbà tí kò sí àlàáfíà.

Ka pipe ipin Jeremáyà 8