Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 7:12-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. “ ‘Ẹ lọ nísinsìn yìí sí ṣílò níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Ísírẹ́lì tí í ṣe ènìyàn mi.

13. Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn

14. Nítorí náà, èmi yóò ṣe ohun tí mo ṣe sí ṣílò sí ilé náà tí a fi orúkọ mi pè, ilé Tẹ́ḿpìlì nínú èyí tí ẹ ní ìgbàgbọ́, àyè tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba yín.

15. Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Éfúráímù.’

16. “Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ.

17. Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní òpópó Jérúsálẹ́mù?

18. Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná síi, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn Ọlọ́run àjòjì láti mú mi bínú sókè.

19. Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni Olúwa wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn?

20. “ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí: Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èṣo orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa.

21. “ ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí: Tẹ̀ṣíwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yóòkù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnra yín.

22. Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba-ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán.

23. Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé: Gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Má a rìn ní ojú ọ̀nà tí mo paláṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín.

24. Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetí sílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀ṣíwájú wọ́n ń rẹ̀yìn.

25. Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Éjíbítì títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín.

26. Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀. Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn.’

27. “Nígbà tí wọ́n bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn.

28. Nítorí náà, sọ fún wọn pé ‘Èyí ni orílẹ̀ èdè tí kò gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn

29. ṣe irun yín kí ẹ sì dàanù, pohùnréré ẹkún lorí òkè aṣálẹ̀, nítorí Olúwa ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremáyà 7