Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:46-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

46. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrútàbí kí o bẹ̀rù nígbà tía bá gbọ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa;àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí,òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipání ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì.

47. Nítorí ìgbà náà yóò wádandan nígbà tí èmiyóò fi ìyà jẹ àwọnòrìṣà Bábílónì, gbogbo ilẹ rẹ̀ ni a ó dójú tìgbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárin rẹ̀.

48. Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn,yóò sì kọrin lórí Bábílónì:nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,”ni Olúwa wí.

49. “Gẹ́gẹ́ bí Bábílónì ti mú kí àwọn olùpa Ísírẹ́lì ṣubúbẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní àwọn olùpa gbogbo ilẹ̀ ayé yóò ṣubú.

50. Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró:Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè,ẹ sì jẹ́ kí Jérúsálẹ́mù wá sí ọkàn yín.”

51. “Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn:ìtìjú ti bò wá lójúnítorí àwọn àlejò wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”

52. “Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,“tí èmi yóò se ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fífin rẹ̀:àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa gbin já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀

53. Bí Bábílónì tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run,bí ó sì ṣe ìlú olodi ní òkè agbára rẹ,síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá,”ní Olúwa wí.

54. “Ìró igbe láti Bábílónì,àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kálídéà!

55. Nítorí pé Olúwa ti ṣe Bábílónì ní ìjẹ,ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀;rírú wọn sì ń hó bi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.

56. Nítorí pé afiniṣe ìjẹ dé sórí rẹ̀,àní sórí Bábílónì;a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn:nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa,yóò san án nítòótọ́.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51