Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:34-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. “Nebukadinésárì Ọba Bábílónì tó jẹ wá run,ó ti mú kí ìdààmú bá wa,ó ti sọ wá di àgbá òfìfo.Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì.Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀,lẹ́yìn náà ni “Ó pọ̀ wá jáde.

35. Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe síẹran ara wa wà lórí Bábílónì;”èyí tí àwọn ibùgbé Síónì wí.“Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogboàwọn tí ń gbé Bábílónì,”ni Jérúsálẹ́mù wí.

36. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí:“Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lóríohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san,èmi yóò mú kí omi òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ.

37. Bábílónì yóò parun pátapáta,yóò sì di àwọn akáta,ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.

38. Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramùbí ọmọ kìnìún.

39. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè,èmi yóò se àsè fún wọn,èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó débití wọn yóò máa kọ ẹ̀rín lẹ́yìn náà,wọn yóò sun oorun àsùnjí,”ni Olúwa wí.

40. “Èmi yóò fà wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́àgùntàn tí a fẹ́ pa, gẹ́gẹ́ bí àgbò àti ewúrẹ́.

41. “Bí Sésákì yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé.Irú ìpàyà wo ni yóò báBábílónì láàrin àwọn orílẹ̀ èdè!

42. Òkun yóò ru borí Bábílónì,gbogbo rírú rẹ̀ yóò borí Bábílónì.

43. Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro,ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ tí ènìyànkò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò.

44. Èmi yóò fi ìyà jẹ Bélì tiBábílónì àti pé èmi yóòjẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì.Orílẹ̀ èdè kò ní i jẹ́ ìṣàn fún-un mọ́.Odi Bábílónì yóò sì wó.

45. “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ẹ̀yin ènìyàn mi!Sá àṣálà fún ẹ̀mi rẹ!Sá fún ìbínú ńlá Ọlọ́run.

46. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrútàbí kí o bẹ̀rù nígbà tía bá gbọ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa;àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí,òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipání ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51