Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 51:29-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ilẹ̀ wárìrì síhìn ín sọ́hùn ún, nítorí péète Olúwa, sí Bábílónì dúróláti ba ilẹ̀ Bábílónì jẹ́ lọ́nàtí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́.

30. Gbogbo àwọn jagunjagunBábílónì tó dáwọ́ ìjà dúró la sí àgọ́ wọn.Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin.Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun,gbogbo irin ẹnu ọ̀nà wọn ti di fífọ́.

31. Iránsẹ́ kan ń tẹ̀lé òmírànláti sọ fún Ọba Bábílónì pégbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn.

32. Odò tí ó ṣàn kọjá kò ṣàn mọ́ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”

33. Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ nìyìí:“Ọmọbìnrin Bábílónì dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.”

34. “Nebukadinésárì Ọba Bábílónì tó jẹ wá run,ó ti mú kí ìdààmú bá wa,ó ti sọ wá di àgbá òfìfo.Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì.Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀,lẹ́yìn náà ni “Ó pọ̀ wá jáde.

35. Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe síẹran ara wa wà lórí Bábílónì;”èyí tí àwọn ibùgbé Síónì wí.“Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogboàwọn tí ń gbé Bábílónì,”ni Jérúsálẹ́mù wí.

36. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí:“Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lóríohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san,èmi yóò mú kí omi òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ.

37. Bábílónì yóò parun pátapáta,yóò sì di àwọn akáta,ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.

38. Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramùbí ọmọ kìnìún.

39. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè,èmi yóò se àsè fún wọn,èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó débití wọn yóò máa kọ ẹ̀rín lẹ́yìn náà,wọn yóò sun oorun àsùnjí,”ni Olúwa wí.

40. “Èmi yóò fà wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́àgùntàn tí a fẹ́ pa, gẹ́gẹ́ bí àgbò àti ewúrẹ́.

41. “Bí Sésákì yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé.Irú ìpàyà wo ni yóò báBábílónì láàrin àwọn orílẹ̀ èdè!

42. Òkun yóò ru borí Bábílónì,gbogbo rírú rẹ̀ yóò borí Bábílónì.

43. Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro,ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ tí ènìyànkò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò.

Ka pipe ipin Jeremáyà 51