Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 49:18-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sódómùàti Gòmórà pẹ̀lú àwọn ìlútí ó wà ní àyíká rẹ,”ní Olúwa wí.“Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀;kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.

19. “Bí kìnnìún ti ń bọ̀ láti igbóJódánì wá sí pápá oko ọlọ́rà áèmi yóò lé Édómù láti ibi ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.Ta ni ẹni náà tí èmi yóò yàn fún èyí?Ta lo dàbí èmi, ta ni ó le pè mí níjà?Ta ni olùsọ́ àgùntàn náà tí ó lè dúró níwájú mi?”

20. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí Olúwa ní fún Édómù, ohun tíó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Témánì.Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde.Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.

21. Nípa ìṣubú ariwo wọn, ilẹ̀yóò mì, a ó gbọ́ igbe wọnní òkun pupa.

22. Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀,yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bóráṣà.Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagunÉdómù yóò dàbí ọkan obìnrin tí ń rọbí.

23. Nípa Dámásíkù:“Inú Hámátì àti Árípádì bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,wọ́n sì dààmú bí omi òkun.

24. Dámásíkù di aláìlera, ó pẹ̀yindàláti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a,ìbẹ̀rù àti ìrora dì í mú, ìrorabí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.

25. Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;ìlú tí mo dunnú sí.

26. Lóòtọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹyóò ṣubú lójú pópó, gbogboàwọn ọmọ ogun rẹ yóò paẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”ní Olúwa àwọn ọmọ ogun wí.

27. “Èmi yóò fi iná sí odi Dámásíkù,yóò sì jó gbọ̀ngàn Bẹni-hádádì run.”

28. Nípa Kédárì àti ìjọba Ásọ́rì èyí ti Nebukadinésárì Ọba Bábílónì dojú ìjà kọ:Èyí ni ohun tí Olúwa sọ:“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ kédárì,kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà oòrùn run.

29. Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọnyóò di gbígbà; ilé wọn yóò diìsínípò padà pẹ̀lú ẹrù àti ràkúnmí wọn.Àwọn ọkùnrin yóò ké pè wọ́n;‘Ìparun ní ibi gbogbo.’

30. “Sálọ kíákíá, dúró nínú ihòìwọ tí ò ń gbé Ásórì,”báyìí ni Olúwa wí.“Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti dojú ìjà kọ ọ́.

31. “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀ èdèkan pẹ̀lú ìrọ̀rùn, èyítí ó dúró pẹ̀lú ìgboyà;”báyìí ní Olúwa wí.“Orílẹ̀ èdè tí kò ní yálà gbàgede tàbí irin,àwọn ènìyàn re ń dágbé.

Ka pipe ipin Jeremáyà 49