Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 42:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Wòlíì Jeremáyà sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe bèèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.”

5. Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremáyà wí pé, “Kí Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrin wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa.

6. Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa; èyí tí àwa ń rán ọ sí; Kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

7. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé;

8. Nígbà náà ni a ó pa Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀; àti gbogbo àwọn ènìyàn láti orí ẹní tí ó kéré dé orí ẹni ńlá.

9. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì wí: ‘Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ ṣíwájú mi.

10. Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkan padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín.

11. Ẹ má ṣe bẹ̀rù Ọba Bábílónì tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbàyín ní ọwọ́ rẹ̀.

12. Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’

13. “Àmọ́ ṣá, bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí,’ ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín.

Ka pipe ipin Jeremáyà 42