Ẹ má ṣe bẹ̀rù Ọba Bábílónì tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbàyín ní ọwọ́ rẹ̀.