Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 36:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ọba sì rán Jéhúdù láti lọ mú ìwé kíká náà wá láti inú iyàrá Elisámà akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí Ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti Ọba.

22. Ó sì jẹ́ ìgbà òtútù nínú oṣù kẹsàn-án, Ọba sì jókòó ní ẹ̀bá iná àrò, iná náà sì ń jó ní iwájú rẹ̀.

23. Nígbà tí Jéhúdù ka ojú ìwé mẹ́ta sí mẹ́rin nínú ìwé náà, Ọba fi ọ̀bẹ gé ìwé, ó sì sọ sínú iná tí ó wà nínú ìdáná, títí tí gbogbo ìwé náà fi jóná tán.

24. Síbẹ̀, Ọba àti gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò bẹ̀rù; wọn kò sì fa aṣọ wọn yá.

25. Elinátanì, Déláyà àti Jemaríà sì bẹ Ọba kí ó má ṣe fi ìwé náà jóná, ṣùgbọ́n Ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn.

26. Dípò èyí Ọba pàṣẹ fún Jeremélì ọmọ Hamelékì, Seráyà ọmọ Ásíráélì àti Selemáyà ọmọ Ábídélì láti mú Bárúkì akọ̀wé àti Jeremáyà wòlíì ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi wọ́n pamọ́.

27. Lẹ́yìn tí Ọba fi ìwé kíkà náà tí ọ̀rọ̀ tí Bárúkì kọ láti ẹnu Jeremáyà jóná tán, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì tọ Jeremáyà wá:

28. “Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jéhóíákímù Ọba Júdà fi jóná.

29. Kí o sì wí fún Jéhóíákímù Ọba Júdà pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èése tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lòótọ́ ni Ọba Bábílónì yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.”

30. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí níti Jéhóíákímù Ọba Júdà pé: Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru.

31. Èmi ó sì jẹ òun àti irú ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ níyà nítorí àìṣedédé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù àti àwọn ènìyàn Júdà, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”

32. Nígbà náà ni Jeremáyà mú ìwé kíká mìíràn fún Bárúkì akọ̀wé ọmọ Neráyà, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremáyà gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jéhóíákímù Ọba Júdà ti sun níná. A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Jeremáyà 36