Dípò èyí Ọba pàṣẹ fún Jeremélì ọmọ Hamelékì, Seráyà ọmọ Ásíráélì àti Selemáyà ọmọ Ábídélì láti mú Bárúkì akọ̀wé àti Jeremáyà wòlíì ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi wọ́n pamọ́.