Ọba sì rán Jéhúdù láti lọ mú ìwé kíká náà wá láti inú iyàrá Elisámà akọ̀wé. Ó sì ka ìwé náà ní etí Ọba àti ní etí gbogbo àwọn ìjòyè tí ó dúró ti Ọba.