Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 32:16-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Bárúkì ọmọkùnrin Néráyà, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé:

17. “Áà! Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbogbo, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe.

18. O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀gbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́rùn títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ.

19. Títóbi ni iṣẹ́ rẹ, agbára sì ni ìṣe rẹ. Ojú rẹ sí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọkùnrin, ó sì fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti ìwà rẹ̀.

20. O ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá ní Éjíbítì. O sì ń ṣe é títí di òní ní Ísírẹ́lì àti lára ọmọ ènìyàn tí ó sì ti gba òkìkí tí ó jẹ́ tìrẹ.

21. O kó àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ jáde láti Éjíbítì pẹ̀lú àmì àti ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá.

22. Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.

23. Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o paláṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.

24. “Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe korájọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kálídéà tí ń gbógun tì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i.

25. Ṣíbẹ̀ à ò fi ìlú náà fún àwọn ará Kálídéà. Ìwọ Olúwa Ọba sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 32