Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 30:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé:

2. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan.

3. Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”

4. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Ísírẹ́lì àti Júdà:

5. “Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrìláìṣe igbe àlàáfíà.

6. Béèrè kí o sì rí:Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrintí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,tí ojú gbogbo wọn sì fàro fún ìrora?

7. Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jákọ́bùṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.

8. “ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa wí pé;‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn,Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù.Àwọn alejo kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́

9. Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọnàti Dáfídì gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn,ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.

10. “ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi,má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì,’ni Olúwa wí.‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jínjìn wá,àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn.Jákọ́bù yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà,kò sì sí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.

Ka pipe ipin Jeremáyà 30