Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 27:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. ‘Èmi kò rán wọn ni Olúwa wí. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín.’ ”

16. Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Bábílónì,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn.

17. Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin Ọba Bábílónì, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ẹ̀yin yóò fi di ìdíbàjẹ́?

18. Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Júdà àti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.

19. Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa àwọn opó, omi òkun níti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti níti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní orílẹ̀ èdè náà.

20. Èyí tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì kò kó lọ nígbà tí ó mú Jéhóíákímù Ọba Júdà lọ sí ìgbèkùn láti Jérúsálẹ̀mù lọ sí Bábílónì, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

21. Lóòótọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí nípa àwọn ohun ìṣúra tí ó ṣẹ́kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin Ọba Júdà àti ní Jérúsálẹ́mù:

22. ‘A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Bábílónì, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa. ‘Lẹ́yìn èyí, mà á mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 27