Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 14:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.

16. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jérúsálẹ́mù torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

17. “Sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn báyìí pé:“ ‘Jẹ́ kí omijé dà lójú milọ́sàn-án àti lóru láìdúró.Fún wúndíá mi-àwọn ènìyàn mití a dá lọ́gbẹ́ àti lílù bolẹ̀.

18. Bí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè náà,Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.Wòlíì àti Àlùfáàti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

19. Ṣé o ti kọ Júdà sílẹ̀ pátapáta ni?Ṣé o ti sá Síónì tì?Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójútí a kò fi le wò wá sàn?A ń retí àlàáfíàṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,ní àsìkò ìwòsànìpáyà là ń rí.

20. Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi waàti àìṣedédé àwọn baba wa;lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.

21. Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dákí o má ṣe dà á.

22. Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀ èdè le ṣe kí òjò rọ̀?Ǹjẹ́ àwọ̀sánmọ̀ fúnra rẹ̀ rọ òjò bí?Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

Ka pipe ipin Jeremáyà 14