Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 8:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu ọ̀nà ibi pẹpẹ.

6. Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe-ohun ìríra ńlá tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ ó tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù yí lọ.”

7. Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.

8. Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.

9. Ó sì wí fún mi pé, “Wọlé kí o rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.”

10. Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí wọ́n yà sára ògiri.

11. Níwájú wọn ni àádọ́rin (70) ọkùnrin tó jẹ́ àgbà ilé Ísírẹ́lì dúró sí, Jáásáníà ọmọ Sáfánì sì dúró sáàrin wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.

12. Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘Olúwa kò rí wa; Olúwa ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ”

13. Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun mìíràn tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

14. Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Támúrì.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 8