Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 6:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:

2. “Ọmọ ènìyàn, dojú kọ àwọn òkè Ísírẹ́lì; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí wọn

3. wí pé: ‘Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí ẹ̀yin òkè ńlá àti àwọn òkè kékèké sí àwọn odò ṣíṣàn àti sí àfonífojì, n ó mú idà wa sórí yín, n ó sì pa ibi gíga yín run.

4. N ó wó pẹpẹ yín lulẹ̀, n ó sì fọ́ pẹpẹ tùràrí yín túútúú; èmi ó sì pa àwọn ènìyàn yín síwájú àwọn òrìṣà wọn.

5. N ó tẹ́ òkú àwọn ará Ísírẹ́lì síwájú òrìsà wọn n ó sì fọ́n egungun wọn yí pẹpẹ wọn ká.

6. Gbogbo ibi tí ẹ ń gbé àti àwọn ibi gíga yín ni yóò di píparun, gbogbo pẹpẹ yín ni yóò di ahoro, àwọn òrìṣà yín yóò di fífọ́ túútúú, àwọn pẹpẹ tùràrí yín ni a ó gé lulẹ̀, gbogbo iṣẹ́ yín yóò parẹ́.

7. Àwọn ènìyàn yín yóò ṣubú láàrin yín, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

8. “ ‘Ṣùgbọ́n n ó dá àwọn kan sí nítorí pé díẹ̀ nínú yín ni yóò bọ́ lọ́wọ́ idà, nígbà tí a bá fọ́n yín ká sí gbogbo ilẹ̀ àti orílẹ̀ èdè.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 6