Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 48:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Èyí yóò jẹ́ ìpín ibi mímọ́ fún àwọn àlùfáà. Yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn ní ìhà àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà oòrùn, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn ní ìhà gúsù. Ní àárin gbùngbùn rẹ̀ ní ilé fún Olúwa yóò wà.

11. Èyí yóò wà fún àwọn àlùfáà tí a yà sí mímọ́, àwọn Sódókítì tí wọn jẹ́ olóòótọ́ nínú sí sin mí, ti wọn kò sì sáko lọ bí ti àwọn Léfì ṣe se nígbà tí àwọn Ísírẹ́lì sáko lọ.

12. Èyí yóò jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì fún wọn láti ara ìpín ibi mímọ́ ilẹ̀ náà, ìpín tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, tí ó jẹ́ ààlà agbégbé àwọn Léfì.

13. “Lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbégbé àwọn àlùfáà, àwọn Léfì yóò pín ìpín kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀. Gígùn rẹ̀ ní àpapọ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹẹdọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, àti fífẹ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́.

14. Wọn kò gbọdọ̀ tà tàbí jìrọ̀ ìkankan nínú rẹ̀. Èyí yìí ni ó dára jùlọ lára ilẹ náà, a kò sì gbọdọ̀ fifún ẹlòmíràn nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa.

15. “Agbègbẹ tí o ṣẹ́kù, tí ń ṣe ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, yóò wà fun àjùmọ̀lò àwọn ará ìlú ńlá náà fún ilé gbígbé àti fún ilẹ̀ ìjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sàn. Ìlú ńlá náà yóò wà ní àárin rẹ̀,

16. Ìwọ̀nyí sì ní bi a ṣe wọ̀n ọ́n: ní ìhà àríwá ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ni ìhà gúsù ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ní ìhà ìlà oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ àti ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́.

17. Ilẹ̀ ìjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn fún ìlú ńlá náà yóò jẹ igba àti àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà gúsù, ìgbà àti ìgbà pẹ̀lú àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.

18. Èyí tí ó kù ní agbégbé náà, tí ó jẹ́ ààlà ìpín ibi mímọ́, gígùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Ìpèsè rẹ̀ yóò fi kún oúnjẹ fún àwọn òsísẹ́ ìlú ńlá náà.

19. Àwọn òsìsẹ́ láti ìlú ńlá náà, tí ó ń dáko níbẹ̀ yóò wá láti gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

20. Gbogbo ìpín náà yóò rí bákan náà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ẹgbẹ kọ̀ọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì ìwọ yóò fi ìpín ibi mímọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan, papọ̀ mọ́ ohun ìní ìlú ńlá náà.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 48