Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 44:2-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Olúwa sọ fún mi, “Ẹnu ọ̀nà yìí ni kí ó wà ní títì. A kò gbọdọ̀ sí i sílẹ̀; kò sí ẹni tí o gbọdọ̀ gba ibẹ̀ wọlé. Ó gbọdọ̀ wà ní títì nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí gbà ibẹ̀ wọlé.

3. Ọmọ aládé fúnra rẹ̀ ní o lè jókòó ní ẹnu ọ̀nà náà kí o sì jẹun níwájú Olúwa. Ó gbọdọ̀ gba ọ̀nà ìlóro ẹnu ọ̀nà wọlé kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.”

4. Lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà àríwá lọ sí iwájú ilé Ọlọ́run. Mo wò ó mo sì rí ògo Olúwa tí ó kún inú ilé Olúwa, mo sì dojúkọ ilẹ.

5. Olúwa sì sọ fún mì pé, “Ọmọ ènìyàn, wò dáadáa, fetí sílẹ̀ dáadáa kí o sì fiyèsí ohun gbogbo tí mo sọ fún ọ nípa ofin lórí ilé Olúwa náà. Fiyèsí ẹnu ọ̀nà ilé Ọlọ́run náà àti gbogbo àbájáde ibi mímọ́.

6. Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí: Ìwà ìríra rẹ tí tó gẹ́ẹ́, ìwọ ilé Ísírẹ́lì!

7. Ní àfikún pẹ̀lú gbogbo àwọn ìwà ìríra rẹ tí ó kù, ìwọ mú àwọn àjòjì aláìkọlà àyà àti ara wá sí inú ibi mímọ́ mi, ní lílo ilé mi ní ìlòkúlò nígbà tí ìwọ fi oúnjẹ fún mi, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ìwọ sì ba májẹ̀mú mi jẹ́.

8. Dípò kí ìwọ pa òfin mi mọ́, ìwọ fi àwọn mìíràn sí ibi mímọ́ mi.

9. Èyí yìí ní Olúwa Ọba wí: Àjòjì aláìkọlà àyà àti ara kò gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi, àti pẹ̀lú àwọn àjòjì tí ń gbé ní àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

10. “ ‘Àwọn Léfì tí wọn rìn jìnnà kúrò lọ́dọ̀ mi nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sìnà, ti wọ́n sì ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi láti tọ àwọn ère wọn lẹ́yìn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀sẹ̀ wọn.

11. Wọn le sìn mi ní ibi mímọ́ mi, kí wọn ṣe ìtọ́jú àwọn ẹnu ọ̀nà ilé Ọlọ́run, kí wọn sì ṣe ìránṣẹ́ nínú rẹ̀; wọn le pa ẹbọ sísun, ki wọn sì rúbọ fún àwọn ènìyàn, kí wọn sì dúró níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

12. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Ísírẹ́lì subú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Ọba sọ.

13. Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti se ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ ìkankan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 44