Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 40:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá. Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká; ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà,

18. O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígun rẹ̀: èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀.

19. Lẹ́yìn náà, o wọn jíjìnna rẹ̀ láti inú ìsàlẹ̀ ẹnu ọ̀nà títí dé àgbàlá tí inú; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà òòrùn àti tí àríwá.

20. Lẹ́yìn náà, ó wọn gígùn àti ibú ẹnu ọ̀nà tí ó dojú kọ àríwá, à bá wọ àgbàlá.

21. Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà ni wíwọ̀n gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni fífẹ̀.

22. Ojú ihò rẹ̀, àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ àti igi ọ̀pẹ tí iṣe ọ̀sọ́ rẹ̀ ni wọn kàn gẹ́gẹ́ bí tí àwọn ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìlà òòrùn. Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà òdìkejì wọn.

23. Ẹnu ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni àdojúkọ ẹnu ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà òòrùn. Ó wọ̀n láti ẹnu ọ̀nà sí àdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 40