Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 40:14-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ó wọ̀n ọ́n lọ sí àwọn ojú àwọn ìgbéró ògiri gbogbo rẹ̀ yí inú òjú ọ̀nà ó jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́. Ìwọ̀n náà tó àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ àgbàlá.

15. Ìjìnà ẹnu ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèkéé náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.

16. Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká; Awọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé ati láti fèrèsé dé òrùlé.

17. Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá. Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká; ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà,

18. O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígun rẹ̀: èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀.

19. Lẹ́yìn náà, o wọn jíjìnna rẹ̀ láti inú ìsàlẹ̀ ẹnu ọ̀nà títí dé àgbàlá tí inú; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà òòrùn àti tí àríwá.

20. Lẹ́yìn náà, ó wọn gígùn àti ibú ẹnu ọ̀nà tí ó dojú kọ àríwá, à bá wọ àgbàlá.

21. Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà ni wíwọ̀n gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹnu ọ̀nà àkọ́kọ́. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni fífẹ̀.

22. Ojú ihò rẹ̀, àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ àti igi ọ̀pẹ tí iṣe ọ̀sọ́ rẹ̀ ni wọn kàn gẹ́gẹ́ bí tí àwọn ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ ìlà òòrùn. Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà òdìkejì wọn.

23. Ẹnu ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni àdojúkọ ẹnu ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà òòrùn. Ó wọ̀n láti ẹnu ọ̀nà sí àdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

24. Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ gúsù. Ó wọn àtẹ́rígbà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 40