Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 39:8-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ó ń bọ̀! Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́. Èyi yìí ni ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

9. “ ‘Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárin àwọn ìlú tí ó wà ni Ísírẹ́lì yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ—àpáta kékèké àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná.

10. Wọn kò ní nílo láti kó igi jọ láti inú pápá, tàbí gé e láti inú igbó, nítorí pé wọ́n yóò lé òhun ìjà ogun bi epo ìdáná. Wọn yóò sì kógun àwọn tí ó ṣe ìgárá sí wọn, wọn yóò sì bo ilé àwọn tí ó bo ilé wọn, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́.

11. “ ‘Ní ọjọ́ náà èmi yóò sì fi ibi ìsìnkú fún Gógì ní Ísírẹ́lì, ni àfonífojì àwọn ti ó rìn ìrìnàjò lọ sí agbègbè ilà òòrùn òkun. Yóò di ojú ọ̀nà àwọn arìnrìn àjò, nítorí Gógì àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni àwa yóò sin síbẹ̀. Nítorí náà, a óò pè é ní àfonífojì tí Ámónì Gógì.

12. “ ‘Fún oṣù méje ní ilé Ísírẹ́lì yóò fi máa sìn wọ́n láti ṣe àfọ̀mọ́ ilẹ̀ náà.

13. Gbogbo ènìyàn ilẹ náà yóò sìn wọ́n, ọjọ́ tí a yìn mi lógo yóò jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ní Olúwa Ọba wí.

14. “ ‘Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́ lóòrèkóórè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà. Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tó kù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀: Ní ìparí oṣù kéje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn.

15. Bí wọ́n n lọ káàkiri ilẹ̀ náà ọ̀kan nínú wọn rí egungun ènìyàn, oun yóò gbé àmì ńlá kalẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ títí àwọn asìnkú yóò fi sìn ín ní àfonífojì Ámónì Gógì.

16. (Bákan náà ìlú kan tí a ń pè ni Ámónì yóò wà níbẹ̀). Nítorí náà wọn yóò wẹ ilẹ̀ náà:’

17. “Ọmọ ènìyàn èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí pé: pe gbogbo oríṣìíríṣìí ẹyẹ àti gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́ jáde:” kí wọn pé jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè sí ìrúbọ tí mó ń múra rẹ̀ fún ọ, ìrúbọ ńlá náà ní orí òkè gíga tí Ísírẹ́lì. Níbẹ̀ ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀.

18. Ẹ̀yin yóò jẹ ẹran ara àwọn ènìyàn ńlá, ẹ o sì mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ aládé ayé bí ẹni pé wọn jẹ́ àgbò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, ewúrẹ́ àti akọ màlúù gbogbo wọn jẹ́ ẹran Ọlọ́ràá láti Báṣánì

19. Níbi ìrúbọ tí mo ń múra kalẹ̀ fún yín, ẹ̀yin yóò jẹ ọ̀rá títí ẹ̀yin yóò fi jẹ àjẹkì, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ títí ẹ̀yin yóò fi yó.

20. Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́sin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìríṣìí jagunjagun ni Olúwa Ọba sọ.

21. “Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n.

22. Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Ísírẹ́lì yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.

23. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì subú nípasẹ̀ idà.

24. Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ̀ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

25. “Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọba wí: Èmi yóò mú Jákọ́bù padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní iyọ́nú si gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 39