Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 37:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Mo wò ó, ìṣan ara àti ẹran ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn.

9. Lẹ́yìn náà ni ó ṣọ fún mi pé, “Ṣọtẹ́lẹ̀ sí èémí; ṣọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì ṣọ fún un pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè.’ ”

10. Nítorí náà, mo ṣọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn; Wọ́n di alààyè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹṣẹ̀ wọn—pẹ̀lú ìhámọ́ra tí ó pọ̀.

11. Lẹ́yìn náà ó ṣọ fún mi: “Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ni gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì. Wọ́n ṣọ wí pé, ‘Egungun wa ti gbẹ ìrètí wa sì ti lọ; a ti gé wa kúrò.’

12. Nítorí náà ṣọtẹ́lẹ̀, kí o sì ṣọ fun wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: Ẹ̀yin ènìyàn mi, Èmi yóò sí àwọn ibojì yín, èmi yóò sì mú yín wá si ilẹ̀ Isírẹ́lì.

13. Ẹ̀yin o sì mọ̀ èmi ni Olúwa, nígbà tí èmi bá ti sí bojì yín, ẹ̀yin ènìyàn mi, ti èmi bá si mú un yín dìde kúrò nińú bojì yín

14. Èmi yóò fi èémí mi sínú yín, ẹ̀yin yóò sì yè, èmi yóò sì mú kí ẹ fi lélẹ̀ ní ilẹ̀ ẹ̀yín tìkára yín. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti ṣọ̀rọ̀, èmi sì ti ṣe ni Olúwa wí.’ ”

15. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá:

16. “Ọmọ ènìyàn, mú igi pátakó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti Júdà àti ti Ísírẹ́lì tí ó ní àsṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátakó mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Igi tí Éfúraímù jẹ́ ti Jósẹ́fù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’

17. So wọ́n papọ̀ sí ara igi kan nítorí náà wọn yóò di ọ̀kan ní ọwọ́ rẹ.

18. “Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa?’

19. Ṣọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò gba igi Jósẹ́fù—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Éfúráímù—àti ti ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Júdà, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’

20. Gbé igi pátakó tí ó kọ nǹkan síi sókè ní iwájú wọn,

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 37