Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 35:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Èmi yóò mú kí o di ahoro títí láé; Kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

10. “ ‘Nítorí tí ìwọ sọ pé, “Àwọn orílẹ̀ èdè àti ilẹ̀ méjì wọ̀nyí yóò jẹ́ tiwa, àwa yóò sì gbà wọ́n ní ìní,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi Olúwa wà níbẹ̀,

11. nítorí náà níwọ̀n ìgbà tí mo ti wà láàyè, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, èmi yóò hùwà sí ọ ní ìbámu pẹ̀lú ìbínú àti owú tí o fihàn nínú ìkórìíra rẹ sí wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ní àárin wọn, nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ rẹ.

12. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti gbọ gbogbo ohun ẹ̀gàn tí ìwọ ti sọ lòdì sí àwọn òkè Ísírẹ́lì náà. Ìwọ wí pé, “A ti fi wọ́n sílẹ̀ ní ṣíṣọ̀fọ̀, a sì fi fún wa láti pajẹ.”

13. Ìwọ lérí sí mi, ó sì sọ̀rọ̀ lòdì sí mí láìsí ìdádúró, èmi sì gbọ́ ọ.

14. Èyí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Nígbà tí gbogbo ayé bá ń yọ̀, èmi yóò mú kí ó di ahoro

15. Nítorí pé ìwọ ń yọ̀ nígbà tí ìní ilé Ísírẹ́lì di ahoro, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yóò ṣe hùwà sí ọ. Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ òkè Séírì, ìwọ àti gbogbo ará Édómù. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 35