Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 34:15-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

16. Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà. Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó farapa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun. Èmi yóò ṣe olùsọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo.

17. “ ‘Ní tìrẹ, agbo ẹran mi, èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrin àgùntàn kan àti òmíràn, àti láàrin àgbò àti ewúrẹ́.

18. Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù? Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu? Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín?

19. Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀?

20. “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí fún wọn: Wòó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàárin àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù.

21. Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ,

22. Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́. Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrin àgùntàn kan àti òmíràn.

23. Èmi yóò fi olùsọ́ àgùntàn kan ṣe olórí wọn, ìránṣẹ́ mi Dáfídì, oun yóò sì tọ́jú wọn; Òun yóò bọ́ wọn yóò sì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn wọn.

24. Èmi Olúwa yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ìránṣẹ́ mi Dáfídì yóò jẹ́ ọmọ aládé láàárin wọn. Èmi Olúwa ní o sọ̀rọ̀.

25. “ ‘Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, èmi yóò sì gba ilẹ̀ náà kúrò lọ́wọ́ ẹranko búburú, kí wọn kí o lè gbé ní aṣálẹ̀, kí àgùntàn sì gbé ní inú igbó ní àìléwu.

26. Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká. Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò; òjò ìbùkún yóò sì wà.

27. Àwọn igi ìgbẹ́ yóò mú èso wọn jáde, ilẹ̀ yóò sì mu irúgbìn jáde; A óò sì dá ààbò bo àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ náà. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá já àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà àjàgà, tí mo sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó fi wọ́n ṣe ẹrú.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 34