Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 32:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀runni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ rẹ,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí

9. Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rúnígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wání àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọkò í tí ì mọ̀.

10. Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rù bà ọ́,àwọn Ọba wọn yóò sì wárìrì fúnìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ,nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọnNí ọjọ́ ìṣubú rẹìkọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrìní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

11. “ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:“ ‘Idà Ọba Bábílónìyóò wá sí orí rẹ,

12. Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ótí ipa idà àwọn alàgbà ènìyàn ṣubúàwọn orílẹ̀ èdè aláìláàánú jùlọ.Wọn yóò tú ìgbéraga Éjíbítì ká,gbogbo ìjọ rẹ ní a óò dá ojú wọn bolẹ̀.

13. Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóòparun ní ẹgbẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omikì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni arọ̀fọ̀.

14. Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòròkí àwọn odò rẹ̀ kí o ṣàn bí epo,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

15. Nígbà tí mo bá sọ Éjíbítì di ahoro,tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò.Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀,nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

16. “Èyí yìí ni ẹkún tí a óò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè yóò sun ún; nítorí Éjíbítì àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

17. Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá:

18. “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún ìjọ Éjíbítì kí o sì ránsẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò.

19. Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ ìwọ ní ojú rere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárin àwọn aláìkọlà náà.’

20. Wọn yóò ṣubú láàárin àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Éjíbítì kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀.

21. Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Éjíbítì àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’

22. “Ásíríà wà níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo jagun jagun rẹ̀; àwọn isà òkú àwọn tí a ti pa sì yí i ká, gbogbo àwọn tí ó ti ipa idà ṣubú.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 32