Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 3:2-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà.

3. Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwe tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.

4. Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsinyìí bámi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ìle Ísírẹ́lì.

5. A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ni mo rán ọ sí

6. kì í ṣe sí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń sọ àjèjì èdè tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn le fún ọ láti gbọ́ yé. Dájúdájú bí mo bá rán ọ sí wọn, wọn ì bá sì fetí sílẹ̀ sí ọ.

7. Ṣùgbọ́n ilé Ísírẹ́lì kò fẹ́ gbọ́ tìrẹ nítorí pé wọn kò fẹ́ láti gbọ́ tèmi, torí pé aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì.

8. Ṣùgbọ́n bí i ti wọn lèmi náà yóò ṣe jẹ́ kí ojú àti ọkàn rẹ le.

9. Èmi yóò ṣe iwájú orí rẹ bí òkúta tó le jùlọ àni tó le ju òkúta ìbọn lọ. Má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí jẹ́ kí wọn ó dáyà já ọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.”

10. Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, kí o sì gba gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sí ọkàn rẹ.

11. Lọ nísinsìnyìí sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ tó wà ní ìgbèkùn. Sọ fún wọn pé báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí yálà wọ́n gbọ́ tàbí wọn kò gbọ́.”

12. Nígbà náà ni Ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi-tó sọ pé, kí a gbé ògo Olúwa ga láti ibùgbé rẹ̀ wá!

13. Bẹ́ẹ̀ ni mo tún gbọ́ ariwo ìyẹ́ apá àti kẹ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà pẹ̀lú ariwo tó dàbí àrá ńlá.

14. Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle Olúwa ni ara mi.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 3