Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 28:16-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹìwọ kún fún ìwà ipá;ìwọ sì dẹ́sẹ̀Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nùbí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.Èmi sì pa ọ run,ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárin òkúta amúbínà

17. Ọkàn rẹ gbéraganítorí ẹwà rẹ.Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́nítorí dídára rẹ.Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;mo sọ ọ di awò ojú níwájú àwọn ọba.

18. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìsòótọ́ rẹìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá látiinú rẹ, yóò sì jó ọ run,èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.

19. Gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó mọ̀ ọ́ní ẹnu ń yà sí ọ;ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rùìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé.’ ”

20. Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

21. “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sídónì; kí o sì ṣọtẹ́lẹ̀ sí i

22. Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sídónì,a ó sì ṣe mí lógo láàárin rẹ.Wọn yóò, mọ̀ pé èmi ní Olúwa,Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹtí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,

23. Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-àrùn sínú rẹèmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn ní ìgboro rẹẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárin rẹpẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.

24. “ ‘Kì yóò sì sí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run.

25. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Nígbà tí èmi yóò bá ṣa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàárin wọn lójú àwọn aláìkọlà; Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkalára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jákọ́bù.

26. Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígba tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi sẹ sí ara àwọn tí ń ṣáátá wọn ní gbogbo àyíká wọn; Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 28