Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 27:9-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Àwọn àgbà Gíbálì,àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,gbogbo ọkọ̀ ojú òkunàti àwọn atukọ̀-òkunwá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

10. “ ‘Àwọn ènìyàn Páṣíà, Lídíà àti Pútìwà nínú jagunjagun rẹàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ.Wọ́n gbé àpáta àti àsíborí wọn rósára ògiri rẹ,wọn fi ẹwà rẹ hàn.

11. Àwọn ènìyàn Árífádì àti Hélékìwà lórí odi rẹ yíká;àti àwọn akọni Gámádì,wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;wọn ti mú ẹwà rẹ pé.

12. “ ‘Táṣíṣì ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin tanúnganran àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.

13. “ ‘Àwọn ará Gíríkì, Túbálì, Jáfánì àti Méṣékì, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàsípààrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.

14. “ ‘Àwọn ti ilé Béti Tógárímà ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin-ogun àti ìbàákà ṣòwò ní ọjà rẹ.

15. “ ‘Àwọn ènìyàn Ródísì ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ onibárà rẹ̀; wọ́n mú eyín-erin àti igi ébónì san owó rẹ.

16. “ ‘Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.

17. “ ‘Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn; pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

18. “ ‘Dámásíkù, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helíbónì, àti irun àgùntàn funfun.

19. “ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.

20. “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

21. “ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.

22. “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣébà àti Rámà, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

23. “ ‘Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ.

24. Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.

25. “ ‘Àwọn ọkọ̀ Táṣíṣì ní èròní ọjà rẹa ti mú ọ gbilẹ̀a sì ti ṣe ọ́ lógoní àárin gbungbun òkun

26. Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọwá sínú omi ńlá.Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ní àárin gbùngbùn òkun.

27. Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,àwọn atọ́kọ̀ rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.Àwọn oníbárà rẹ àti gbogbo àwọnjagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹàti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹtí ó wà ní àárin rẹyóò rì sínú àárin gbùngbùn òkunní ọjọ́ ìparun rẹ.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 27