Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 26:7-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “Nítorí báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, Ọba àwọn Ọba, dide sí Tírè pẹ̀lú ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun.

8. Yóò sì fi idà ṣá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkítì tì ọ́, yóò sì gbé apata sókè sí ọ.

9. Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀.

10. Àwọn ẹsin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti o di fífọ́ pátapáta.

11. Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀.

12. Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú òkun.

13. Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́.

14. Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Ọlọ́run wí.

15. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí sí Tírè: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń sẹlẹ̀ ní inú rẹ?

16. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ aládé etíkun yóò sọ̀ kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn tì wọn yóò sì bọ́ àwọn ẹ̀wù wọn tí a ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jòkòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́.

17. Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:“ ‘Báwo ni a se pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkíìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀!Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogboòun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀;ìwọ gbé ẹ̀rù rẹlórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.

18. Nisin yìí erékùṣù wárìrìní ọjọ́ ìṣubú rẹ;erékùṣù tí ó wà nínú òkunni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’

19. “Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́,

20. nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ ibi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

21. Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì sí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, ṣíbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Ọlọ́run wí.”

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 26