Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 22:15-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Èmi yóò tú kán ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ.

16. Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

17. Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

18. “Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ti di ìdárọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, tánúnganran, ìrin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà.

19. Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdárọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jérúsálẹ́mù.

20. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti tánúnganran jọ sínú iná ìléru láti fi amúbí ina yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunnú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárin ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́.

21. Èmi o ko yín jọ, èmi o sì fín iná ibínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrin rẹ̀.

22. Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò se yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ”

23. Lẹ́ẹ̀kan síi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé,

24. “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilẹ̀ náà, ‘Ìwọ ní ilẹ̀ tí kò ti ní rọ òjò tàbí ìrì ní àkókò ìbínú.’

25. Ìdìtẹ̀ sì wà láàrin àwọn ọmọ aládé inú rẹ̀, tó dàbí bíbú kìnnìún tó ń fà ẹ̀ran ya, wọ́n ń ba àwọn ènìyàn jẹ́, wọ́n ń kó ìsúra àti àwọn ohun iyebíye wọ́n sì ń sọ púpọ̀ di opó nínú rẹ̀.

26. Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti rú ofin mi, wọn si ti sọ ohun mímọ́ mi di àìlọ́wọ̀: wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrin ohun mímọ́ àti àìlọ́wọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi ìyàtọ̀ hàn láàrin ohun àìmọ́, àti mímọ́, wọn sì ti fi ojú wọn pamọ́ kúrò ní ọjọ ìsinmi mi, mó sì dí ẹni àìlọ́wọ̀ láàrin wọn.

27. Àwọn ọmọ aládé àárin rẹ̀ dàbí ikokò ti ń ṣọ̀tẹ̀, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìsòótọ́.

28. Àti àwọn wòlíì rẹ̀ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì iran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀sẹ èké sí wọn, wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Ọlọ́run wí’, nígbà tí ó ṣépè Olúwa kò sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 22