Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 20:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nítorí pé wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àsẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn.

17. Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú ihà.

18. Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú ihà pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín tàbí kí ẹ pa òfin wọn mọ́ tàbí kí ẹ bara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn.

19. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́.

20. Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ àmì láàrin wa: ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ọlọ́run yín.”

21. “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mí mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé ń ó tú ìbínú mi lórí wọn N ó sì mú kí ibínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni ihà.

22. Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nitori orúkọ mi mo sì ṣe ohun tí kò ní bá orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn.

23. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú ọwọ ti mo gbé sókè, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún wọn nínú ihà pé n ó tú wọn ka sì àárin àwọn orílẹ̀ èdè, ń ó sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ gbogbo,

24. nítorí pé wọn kò pa òfin mí mọ́, wọn sì tún kọ àsẹ mi sílẹ̀, wọn tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Ọkàn wọn sì dúró ṣinṣin sọ́dọ̀ òrìṣà baba wọn.

25. Èmi náà sì fi wọn fún ìlànà tí kò dára àti òfin tí wọn kò le e yè nípa rẹ̀;

26. Mo jẹ́ kí ó sọ wọn di aláìmọ́ nípa ẹ̀bùn-nipa fífi àkọ́bí ọmọ wọn rú ẹbọ sísun àkọ́bí wọn la iná kọjá, kí ń lè kó ìpayà bá wọn, kí wọn le mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

27. “Nítorí náà ọmọ ènìyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ní ohun ti Olúwa Ọlọ́run wí: Nínú èyí náà, baba yín ti sọ̀rọ̀ àìtọ́ sí mi nípa kíkọ mi sílẹ̀.

28. Nígbà tí mo mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí láti fún wọn, gbogbo igi ilẹ̀ gíga àti gbogbo igi to rúwé ni wọn tí ń rúbọ wọn ṣe irubọ to ń mú mi bínú, níbẹ̀ sì ni wọn ń ṣe òórùn dídùn wọn, ti wọn sì ń ta ọrẹ ohun mímu sílẹ̀.

29. Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé: Kí ní ibi gíga tí ẹ n lọ yìí?’ ” (Wọn sì ń pè ní Bámà di onì yìí.)

30. “Nítorí náà sọ fún ile Ísírẹ́lì: ‘Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Ṣe o fẹ bara rẹ jẹ́ bi àwọn baba rẹ ṣe ṣe, to ń ṣe àgbèrè nípa tí tẹ̀lé àwọn àwòrán ìríra?

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 20