Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 16:35-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. “ ‘Nítorí náà, ìwọ alágbèrè, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

36. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí pé ìwọ tú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ jáde, ìwọ sì fi ìhòòhò rẹ hàn, nípa ṣíṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn olólùfẹ̀ẹ̀ rẹ, àti nítorí gbogbo ère tí o fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ṣe ìrúbọ fún,

37. nítorí náà, Èmi yóò ṣa gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ jọ, pẹ̀lú gbogbo àwọn ti ẹ jọ ṣe fàájì, àwọn tí ìwọ fẹ́ àti àwọn tí ìwọ korìíra. Èmi yóò ṣa gbogbo wọn káàkiri, láti mú wọn lòdì sí ọ, èmi yóò sí aṣọ rẹ, níwájú wọn, wọn yóò sì rí ìhòòhò rẹ.

38. Èmi yóò dá ọ lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti dá obìnrin tó ba ìgbeyàwó jẹ́, tí wọn sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀; Èmi yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ ìbínú àti owú mi wá sórí rẹ.

39. Nígbà náà ni èmi yóò fà ọ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn yóò sì wó gbogbo òkìtì rẹ pẹ̀lú àwọn ojúbọ rẹ palẹ̀. Wọn yóò tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ ni wọn yóò gbà, wọn yóò sì fi ọ sílẹ̀ ní ìhòòhò àti ààbò.

40. Wọn yóò pe àjọ ènìyàn jọ lé ọ lórí, àwọn tí yóò sọ ọ́ ní òkúta, ti wọn yóò sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́.

41. Wọn yóò jo gbogbo ilé rẹ palẹ̀ wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ́ ní ojú àwọn obìnrin. Èmi yóò fi òpin sí àgbèrè ṣíṣe rẹ. Ìwọ kò sì ní san owó fún àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ́.

42. Nígbà náà ni ìbínú mi sí Ọ yóò rọ̀, owú ìbínú mi yóò sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ; inú mi yóò rọ, èmi kò sì ní bínú mọ́.

43. “ ‘Nítorí pé o kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sórí rẹ, ni Olúwa Ọlọ́run wí, Ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ?

44. “ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.”

45. Ọmọ ìyà rẹ ni ọ lóòtọ́, to korìíra ọkọ rẹ àti àwọn ọmọ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ara ilé àwọn arábìnrin rẹ ni ọ nitootọ, àwọn to n korìíra ọkọ wọn sílẹ̀, tó tún ń korìíra àwọn ọmọ. Ará Híítì ni ìyá rẹ, baba rẹ si jẹ́ ara Ámórì.

46. Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaríà, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá aríwá rẹ, Sódómù sì ni àbúrò rẹ, obìnrin tó ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ ni ìhà gúúsù rẹ.

47. Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà irira wọn ṣùgbọ́n ní àárin àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ

48. Olúwa Ọlọ́run wí pé, Bí mo ṣe wà láàyè Sódómù tí í se ẹgbọ́n rẹ obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kò ṣe to ohun tí ìwọ àti ọmọbìnrin rẹ ṣe.

49. “ ‘Wò ó, ẹ̀sẹ̀ tí Sódómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin sẹ̀ nìyìí: Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran talákà àti aláìní lọ́wọ́

50. Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi iwọ ti ròó, nítorí ìgbéraga àti àwọn Ohun ìríra tí wọ́n ṣe.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 16