Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 2:8-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi niàti ẹni tó fún un ní ọkà,ọtí-wáìnì tuntun àti òróróẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Báálì

9. “Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n,èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀.Èmi yóò sì gba ìrun àgùntàn irun àgùtàn àti ọ̀gbọ̀ mi padàmo ti fifun un láti bo ìhòòho rẹ̀.

10. Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hànlójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi

11. Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin:àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀,ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àṣàyàn ọdún rẹ̀.

12. Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run,Èyí tí ó pè ní èrèe rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Olólùfẹ́ rẹ̀,Èmi yóò sọ wọ́n di igbó,àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.

13. Èmi yóò jẹ́ ẹ́ níyà fún gbogbo ọjọ́tó fi jo tùràrí sí Báálìtí ó fi òrùka àti ohun ọ̀ṣọ́ wọ ara rẹ̀ tán,tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ.Ṣùgbọ́n ó gbàgbé èmi,”ni Olúwa wí.

14. “Nítorí náà, èmi yóò tàn ánÈmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀

15. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,Èmi yóò fi àfonífojì Ákórì ṣe ilẹ̀kùn ìrètí fún un.Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Éjíbítì

16. “Yóò si ṣe ní ọjọ́ náàÌwọ yóò pè mí ní ‘Ọkọ mi’;Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’ni Olúwa wí.

17. Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Báálì kúrò lẹ́nu rẹ̀;ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Báálì pè mọ́

Ka pipe ipin Hósíà 2