Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 9:2-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Àwọn Júù pé jọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbégbé ọba Ṣéríṣésì láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojú kọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tó kù ń bẹ̀rù u wọn.

3. Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbéríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Módékáì.

4. Módékáì sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin, òkìkíi rẹ̀ sì tàn jákè jádò àwọn ìgbéríko, ó sì ní agbára kún agbára.

5. Àwọn Júù sì gé gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì run wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n sí àwọn tí ó kóòríra wọn.

6. Ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin run

7. Wọ́n sì tún pa parisánídátà, Dálífónì, Ásípátà,

8. Pórátà, Ádálíyà, Árídátà,

9. Parimásítà, Áríṣáyì, Árídáyì àti Fáíṣátà,

10. Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hámánì, ọmọ Hámédátà, ọ̀ta àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn.

11. Ní ọjọ́ náà gan-an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà wá fún ọba.

12. Ọba sì sọ fún Ẹ́sítà ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ̀gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hámánì ní ilé ìṣọ́ Ṣúṣà run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tó kù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.”

13. Ẹ́sítà sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.”

14. Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Ṣúṣà, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hámánì kọ́.

15. Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Ṣúṣà, Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn.

16. Lákókò yìí, àwọn tó kù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbégbé ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn. Wọ́n sì pa ẹgbàá mẹ́tadínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin (75,000) àwọn tí ó kóòríra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ọ wọn lé ìkógún un wọn.

17. Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àṣè àti ayọ̀.

18. Àwọn Júù tí ó wà ní Ṣúṣà, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ Kẹẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àṣè àti ayọ̀.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 9