Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 8:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Lẹ́ṣẹ̀ kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù sífánì. Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Módékáì sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóṣo baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tadínláàdóje tí ó lọ láti Ińdíà títí ó fi dé kúsì. Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn.

10. Modékáì sì fi àṣẹ ọba Ṣéríṣésì kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán-an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba.

11. Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn; láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀ èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbéríko tí ó bá fẹ́ kọ lù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn; kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀taa wọn.

12. Ọjọ́ tí a yàn fún àwọn Júù ní gbogbo agbégbé ọba Ṣéríṣésì láti ṣe nǹkan yìí ni ọjọ́ kẹtàlá èyí tí í ṣe oṣu kejìlá, oṣù Ádárì.

13. Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbéríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò leè múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀taa wọn.

14. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ ayaba bí àṣà tí wọ́n ń gun ẹṣin ọba, sáré jáde, wọ́n sáré lọ nípa àṣẹ ọba. A sì tún gbé àṣẹ náà jáde ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà.

15. Módékáì sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú eléṣèé àlùkò dáradára, ìlú Ṣúṣà sì ṣe àjọyọ̀ ńlá.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 8