Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 8:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ṣérísésì fún Ésítà ayaba ní ilée Hámánì, ọ̀ta àwọn Júù. Módékáì sì wá síwájú ọba, nítorí Ẹ́sítà ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba.

2. Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ọ Hámánì ó sì fi fún Módékáì, Ẹ́sítà sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olóórí ilée Hámánì.

3. Ẹ́sítà sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hámánì ará Ágágì, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù.

4. Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Ẹ́sítà ó sì dìde, ó dúró níwájúu rẹ̀.

5. Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojú rere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lúu mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hámánì ọmọ Hámédátà, ará Ágágì, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run.

6. Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe fara dàá tí èmi yóò sì rí kí ibi máa ṣubú lu àwọn ènìyàn mi? Báwo ni èmi yóò ṣe fara dàá, tí èmi yóò sì máa wo ìparun àwọn ìdíléè mi?”

7. Ọba Ṣéríṣésì dá Ẹ́sítà ayaba àti Módékáì aráa Júù náà lóhùn pé, “Nítorí Hámánì kọ lu àwọn aráa Júù, èmi ti fi ilée rẹ̀ fún Ẹ́sítà, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 8