Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 7:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ésítà sọ wí pé, “alátakò àti ọ̀ta náà ni Hámánì aláìníláárí yìí,”Nígbà náà ni Hámánì wárìrì níwájú ọba àti ayaba.

7. Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hámánì, ti ríi dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Ẹ́sítà ayaba nítorí ẹ̀míi rẹ̀.

8. Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngán àsè náà, Hámánì ṣubú sórí àga tí Ẹ́sítà ayaba fẹ̀yìntì.Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?”Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hámánì lójú.

9. Nígbà náà Háríbónà ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “igi tí ó ga tó ìwọ̀n mítà mẹ́talélógún (23 mítà) ni Hámánì ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilée rẹ̀. Ó ṣeé fún Módékáì, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.”Ọba wí pé, ẹ ṣo ó rọ̀ sórí i rẹ́!

10. Wọ́n sì ṣo Hámánì sórí igi tí ó ti pèṣè sílẹ̀ fún Módékáì, ìbínú ọba sì rọ̀.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 7