Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 5:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì, ọba tún béèrè lọ́wọ́ Ésítà, “Báyìí pẹ́: kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìwọ ń béèrè fún? Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọbaa mi, a ó fi fún ọ.”

7. Ẹ́sítà sì dáhùn, “Ẹ̀bẹ̀ mi àti ìbéèrè mi ni èyí:

8. Bí ọba bá fi ojú rere rẹ̀ fún mi, tí ó bá sì tẹ́ ọba lọ́rùn láti gba ẹ̀bẹ̀ mi àti láti mú ìbéèrè mi ṣẹ, jẹ́ kí ọba àti Hámánì wá ní ọ̀la sí ibi àṣè tí èmi yóò pèṣè fún wọn. Nígbà náà ni èmi yóò dáhùn ìbéèrè ọba.”

9. Hámánì jáde lọ ní ọjọ́ náà pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí Módékáì ní ẹnu ọ̀nà ọba, ó wòye pé kò dìde tàbí kí ó bẹ̀rù ní iwájú oun, inú bí i gidigidi sí Módékáì.

10. Ṣùgbọ́n, Hámánì kó ara rẹ̀ ní ìjánu, ó lọ sí ilé.Ó pe àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ jọ àti Sérésì ìyàwóo rẹ̀,

11. Hámánì gbéraga sí wọn nípa títóbi ọ̀rọ̀ rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ọ̀nà tí ọba ti bu ọla fún-un àti bí ó ṣe gbé e ga ju àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè tó kù lọ.

12. Hámánì tún fi kún-un pé, “Kìí ṣe èyí nìkan. Èmi nìkan ni ayaba Ẹ́sítà pè láti sin ọba wá sí ibi àsè tí ó sè. Bákan náà, ó sì tún ti pè mí pẹ̀lú ọba ní ọ̀la.

13. Ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò ì tíì tẹ́ mi lọ́rùn níwọ̀n ìgbà tí mo bá sì ń rí Módékáì aráa Júù yẹn tí ó ń jòkòó lẹ́nu ọ̀nà ọba.”

14. Ìyàwó rẹ̀ Ṣérésì àti àwọn ọ̀rẹ́ẹ rẹ̀ wí fún-un pé, “Ri igi kan, kí ó ga tó ìwọ̀n míta mẹ́ta-lélógún, kí o sì sọ fún ọba ní òwúrọ̀ ọ̀la kí ó gbé Módékáì rọ̀ sórí i rẹ̀. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọba lọ sí ibi àṣè pẹ̀lú ayọ̀.” Èrò yí dùn mọ́ Hámánì nínú, ó sì ri igi náà.

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 5