orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,wúrà dídára di àìdán!Òkúta ibi mímọ́ wá túkásí oríta gbogbo òpópó.

2. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Síónì tí ó ṣe iyebíye,tí wọ́n wọn iye wúrà ṣewá dàbí ìkòkò amọ̀ lásániṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!

3. Àwọn ọ̀wàwà pèsè ọmú wọnfún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kànbí ògòǹgò ní aṣálẹ̀.

4. Nítorí òùngbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹṢùgbọ́n kòsí ẹni tí ó fi fún wọn.

5. Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradáradi òtòsì ní òpópó.Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ni wọ́n sùn ní orí òkítì eérú.

6. Ìjìyà àwọn ènìyàn mitóbi ju ti Sódómù lọ,tí a sí nípò ní òjijìláì sí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.

7. Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò dídì,wọ́n sì funfun ju wàrà lọlára, wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa,ìrísí wọn dàbí sáfírè.

8. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí wọ́n dúdú ju èédú;wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó.Ara wọn hun mọ́ egungun;ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.

9. Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sànju àwọn tí ìyàn pa;tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfòfún àìní oúnjẹ láti inú pápá.

10. Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánúni wọ́n ṣe ọmọ wọntí ó di oúnjẹ fún wọnnígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.

11. Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀;ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde.Ó da iná ní Síónìtí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

12. Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,tàbí àwọn ènìyàn ayé,wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọodi ìlú Jérúsálẹ́mù.

13. Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíìàti àìṣedédé àwọn olórí àlùfáà,tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodosílẹ̀ láàrin rẹ̀.

14. Nísinsìnyí wọ́n ń rìn kiri ní òpópóbí ọkùnrin tí ó fọ́jú.Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́ntí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.

15. “Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn.“Ẹlọ! Ẹlọ! Ẹ má se fọwọ́ kàn wá!”Àwọn ènìyàn láàrin orílẹ̀ èdè wí pé,“Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”

16. Olúwa ti tú wọn ká fún-ra-ra-rẹ̀;kò sí bojú tó wọn mọ́.Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́,àti àánú fún àwọn àgbà.

17. Síwájú sí i, ojú wa kùnàfún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán;láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wòfún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.

18. Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri,àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́.Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níyenítorí òpin wa ti dé.

19. Àwọn tí ń lé wa yáraju idì ojú ọ̀run lọ;wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkèwọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní ihà.

20. Ẹni àmì òróró Olúwa, èémí ìyè wa,ni wọ́n fi tàkúté wọn mú.Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ni àwa yóò máa gbé láàrin orílẹ̀-èdè gbogbo.

21. Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Édómù,ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Húsì.Ṣùgbọ́n, a ó gbé aago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú;ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòòhò.

22. Ìwọ ọmọbìnrin Síónì, ìjìyà rẹ yóò dópin;kò ní mú ìgbékùn rẹ pẹ́ mọ́.Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Édómù, yóò jẹ ẹ̀sẹ̀ rẹ níyàyóò sì fi àìṣedédé rẹ hàn kedere.